Saamu 55:16
Psalms 55:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n èmi pe Ọlọ́run; Olúwa yóò sì gbà mí.
Psalms 55:16 in English
Psalms 55:16 · Berean Standard Bible
But I call to God, and the LORD saves me.
Context
14pẹ̀lú ẹni tí èmi ti jẹ ìgbádùn adùn ìdàpọ̀,
bí a ṣe ń rìn pẹ̀lú àwùjọ ní ilé Ọlọ́run. 15Kí ikú kí ó dé bá wọn,
kí wọn ó lọ láààyè sí isà òkú,
jẹ́ kí wọn ó sọ̀kalẹ̀ sí ibojì pẹ̀lú ìpayà,
nítorí tí ìwà búburú ń bẹ ní ibùjókòó wọn, àti nínú wọn. 16Ṣùgbọ́n èmi pe Ọlọ́run;
Olúwa yóò sì gbà mí. 17Ní alẹ́, ní òwúrọ̀ àti ní ọ̀sán
èmi sọkún jáde nínú ìpọ́njú,
o sì gbọ́ ohùn mi. 18Ó rà mí padà láìléwu
kúrò nínú ogun tí ó dìde sí mi,
nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó dìde sí mi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.