Native Bible

Psalms 53:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gbogbo ènìyàn tí ó ti yí padà, wọ́n ti parapọ̀ di ìbàjẹ́; kò sí ẹnìkan tí ó ń ṣe rere, kò sí ẹnìkan.

Psalms 53:3 in English

Psalms 53:3 · Berean Standard Bible

All have turned away, they have together become corrupt;* there is no one who does good, not even one.*

Context

1Aṣiwèrè wí ní ọkàn rẹ̀ pé, “Ọlọ́run kò sí.” Wọ́n bàjẹ́, gbogbo ọ̀nà wọn sì burú; kò sì ṣí ẹnìkan tí ń ṣe rere. 2Ọlọ́run bojú wo ilẹ̀ láti ọ̀run sórí àwọn ọmọ ènìyàn, láti wò bóyá ẹnìkan wà, tí ó ní òye, tí ó sì ń wá Ọlọ́run. 3Gbogbo ènìyàn tí ó ti yí padà, wọ́n ti parapọ̀ di ìbàjẹ́; kò sí ẹnìkan tí ó ń ṣe rere, kò sí ẹnìkan. 4Ṣé àwọn oníṣẹ́ búburú kò ní ìmọ̀? Àwọn ẹni tí ń jẹ ènìyàn mi, bí ẹni jẹun tí wọn kò sì pe Ọlọ́run? 5Níbẹ̀ ni ìwọ gbé wà ní ìbẹ̀rù ńlá níbi tí ẹ̀rù kò gbé sí, nítorí Ọlọ́run tí fọ́n egungun àwọn tí ó dó tì ọ́ ká; ìwọ tí dójútì wọ́n, nítorí Ọlọ́run ti kẹ́gàn wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.