Saamu 53:2
Psalms 53:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọlọ́run bojú wo ilẹ̀ láti ọ̀run sórí àwọn ọmọ ènìyàn, láti wò bóyá ẹnìkan wà, tí ó ní òye, tí ó sì ń wá Ọlọ́run.
Psalms 53:2 in English
Psalms 53:2 · Berean Standard Bible
God looks down from heaven upon the sons of men to see if any understand, if any seek God.
Context
1Aṣiwèrè wí ní ọkàn rẹ̀ pé,
“Ọlọ́run kò sí.”
Wọ́n bàjẹ́, gbogbo ọ̀nà wọn sì burú;
kò sì ṣí ẹnìkan tí ń ṣe rere. 2Ọlọ́run bojú wo ilẹ̀ láti ọ̀run
sórí àwọn ọmọ ènìyàn,
láti wò bóyá ẹnìkan wà, tí ó ní òye,
tí ó sì ń wá Ọlọ́run. 3Gbogbo ènìyàn tí ó ti yí padà,
wọ́n ti parapọ̀ di ìbàjẹ́;
kò sí ẹnìkan tí ó ń ṣe rere, kò sí ẹnìkan. 4Ṣé àwọn oníṣẹ́ búburú kò ní ìmọ̀?
Àwọn ẹni tí ń jẹ ènìyàn mi, bí ẹni jẹun
tí wọn kò sì pe Ọlọ́run?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.