Saamu 51:2
Psalms 51:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wẹ gbogbo àìṣedéédéé mi nù kúrò kí o sì wẹ̀ mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi!
Psalms 51:2 in English
Psalms 51:2 · Berean Standard Bible
Wash me clean of my iniquity and cleanse me from my sin.
Context
1Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run,
gẹ́gẹ́ bí ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ̀,
gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ àánú rẹ̀
kí o sì pa gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi rẹ́. 2Wẹ gbogbo àìṣedéédéé mi nù kúrò
kí o sì wẹ̀ mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi! 3Nítorí mo mọ̀ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi,
nígbà gbogbo ni ẹ̀ṣẹ̀ mi wà níwájú mi. 4Sí ọ, ìwọ nìkan ṣoṣo, ni mo dẹ́ṣẹ̀ sí
ni mo sì ṣe búburú níwájú rẹ̀,
kí a lè dá ọ láre nígbà tí ìwọ bá ń sọ̀rọ̀,
kí o sì le wà láìlẹ́bi, nígbà tí ìwọ bá ń ṣe ìdájọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.