Saamu 51:4
Psalms 51:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Sí ọ, ìwọ nìkan ṣoṣo, ni mo dẹ́ṣẹ̀ sí ni mo sì ṣe búburú níwájú rẹ̀, kí a lè dá ọ láre nígbà tí ìwọ bá ń sọ̀rọ̀, kí o sì le wà láìlẹ́bi, nígbà tí ìwọ bá ń ṣe ìdájọ́.
Psalms 51:4 in English
Psalms 51:4 · Berean Standard Bible
Against You, You only, have I sinned and done what is evil in Your sight, so that You may be proved right when You speak and blameless when You judge.*
Context
2Wẹ gbogbo àìṣedéédéé mi nù kúrò
kí o sì wẹ̀ mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi! 3Nítorí mo mọ̀ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi,
nígbà gbogbo ni ẹ̀ṣẹ̀ mi wà níwájú mi. 4Sí ọ, ìwọ nìkan ṣoṣo, ni mo dẹ́ṣẹ̀ sí
ni mo sì ṣe búburú níwájú rẹ̀,
kí a lè dá ọ láre nígbà tí ìwọ bá ń sọ̀rọ̀,
kí o sì le wà láìlẹ́bi, nígbà tí ìwọ bá ń ṣe ìdájọ́. 5Nítòótọ́, nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni a ti bí mi,
nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni ìyá mí sì lóyún mi. 6Nítòótọ́ ìwọ fẹ́ òtítọ́ ní inú;
ìwọ kọ́ mi ní ọgbọ́n ní ìhà ìkọ̀kọ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.