Saamu 50:5
Psalms 50:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Kó àwọn ènìyàn mímọ́ jọ fún mi àwọn tí wọn fi ẹbọ dá májẹ̀mú fún mi.”
Psalms 50:5 in English
Psalms 50:5 · Berean Standard Bible
“Gather to Me My saints, who made a covenant with Me by sacrifice.”
Context
3Ọlọ́run ń bọ̀,
bẹ́ẹ̀ ni kì yóò dákẹ́,
iná yóò máa jó níwájú rẹ̀,
àti ní àyíká rẹ̀ ni ẹ̀fúùfù líle yóò ti máa jà ká. 4Yóò sì pe àwọn ọ̀run láti òkè wá jọ àti ayé,
kí o le máa ṣe ìdárò àwọn ènìyàn rẹ̀. 5“Kó àwọn ènìyàn mímọ́ jọ fún mi
àwọn tí wọn fi ẹbọ dá májẹ̀mú fún mi.” 6Àwọn ọ̀run yóò sì sọ̀rọ̀ òdodo rẹ̀,
nítorí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni onídàájọ́. 7“Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ènìyàn mi, èmi yóò si sọ̀rọ̀, ìwọ Israẹli, èmi yóò jẹ́rìí sí ọ:
èmi ní Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.