Native Bible

Psalms 5:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí ìwọ kì í ṣe Ọlọ́run tí ó ní inú dídùn sí búburú; bẹ́ẹ̀ ni ẹni ibi kò le è bá ọ gbé.

Psalms 5:4 in English

Psalms 5:4 · Berean Standard Bible

For You are not a God who delights in wickedness; no evil can dwell with You.

Context

2Fi etí sílẹ̀ sí igbe mi fún ìrànlọ́wọ́, ọba mi àti Ọlọ́run mi, nítorí ìwọ ni mo gba àdúrà sí. 3Ní òwúrọ̀, Olúwa, ìwọ yóò gbọ́ ohùn mi; ní òwúrọ̀, èmi yóò gbé ẹ̀bẹ̀ mi sí iwájú rẹ̀ èmi yóò sì dúró ní ìrètí. 4Nítorí ìwọ kì í ṣe Ọlọ́run tí ó ní inú dídùn sí búburú; bẹ́ẹ̀ ni ẹni ibi kò le è bá ọ gbé. 5Àwọn agbéraga kò le è dúró níwájú rẹ̀. Ìwọ kórìíra gbogbo àwọn aṣebi; 6ìwọ yóò pa àwọn tí ń ṣe èké run. Apani àti ẹni ẹ̀tàn ènìyàn ni Olúwa yóò kórìíra.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.