Saamu 49:17
Psalms 49:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí kì yóò mú ohun kan lọ nígbà tí ó bá kú, ògo rẹ̀ kò ní bá a sọ̀kalẹ̀ sí ipò òkú.
Psalms 49:17 in English
Psalms 49:17 · Berean Standard Bible
For when he dies, he will carry nothing away; his abundance will not follow him down.
Context
15Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò ra ọkàn mi padà
kúrò nínú isà òkú,
yóò gbé mi lọ sọ́dọ̀ òun fún rara rẹ̀. 16Má ṣe bẹ̀rù nígbà tí ẹnìkan bá di ọlọ́rọ̀.
Nígbà tí ìyìn ilé rẹ̀ ń pọ̀ sí i. 17Nítorí kì yóò mú ohun kan lọ nígbà tí ó bá kú,
ògo rẹ̀ kò ní bá a sọ̀kalẹ̀ sí ipò òkú. 18Nígbà tí ó wà láyé, ó súre fún ọkàn ara rẹ̀.
Àwọn ènìyàn yìn ọ́ nígbà tí ìwọ ṣe rere. 19Òun yóò lọ sí ọ̀dọ̀ ìran àwọn baba rẹ̀
àwọn tí ki yóò ri ìmọ́lẹ̀ ayé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.