Saamu 46
Psalms 46 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
1Ọlọ́run ni ààbò àti agbára wa
ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ ní ìgbà ìpọ́njú. 2Nítorí náà àwa kì yóò bẹ̀rù, bí a tilẹ̀ ṣí ayé ní ìdí,
tí òkè sì ṣubú sínú Òkun. 3Tí omi rẹ̀ tilẹ̀ ń hó tí ó sì ń mì
tí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ń mì pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ̀. Sela. 4Odò ńlá kan wà tí ṣíṣàn rẹ̀ mú inú ìlú Ọlọ́run dùn,
ibi mímọ́, níbi ti Ọ̀gá-ògo ń gbé. 5Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀, kò ní yẹ̀:
Ọlọ́run yóò ràn án lọ́wọ́ ní kùtùkùtù òwúrọ̀. 6Àwọn orílẹ̀-èdè ń bínú, àwọn ilẹ̀ ọba ṣubú,
ó gbé ohun rẹ̀ sókè, ayé yọ̀. 7Olúwa àwọn ọmọ-ogun wà pẹ̀lú wa,
Ọlọ́run Jakọbu ni ààbò wa. 8Ẹ wá wo iṣẹ́ Olúwa
irú ahoro tí ó ṣe ní ayé. 9O mú ọ̀tẹ̀ tán de òpin ilẹ̀ ayé
ó ṣẹ́ ọrun, ó sì gé ọ̀kọ̀ sí méjì
ó fi kẹ̀kẹ́ ogun jóná. 10Ẹ dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ní Ọlọ́run.
A ó gbé mi ga nínú àwọn orílẹ̀-èdè,
a ó gbé mi ga ní ayé. 11Olúwa àwọn ọmọ-ogun wà pẹ̀lú wa;
Ọlọ́run Jakọbu sì ni ààbò wa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.