Saamu 47
Psalms 47 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
1Ẹ pàtẹ́wọ́, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn
ẹ hó sí Ọlọ́run pẹ̀lú orin ayọ̀ tó rinlẹ̀. 2Báwo ni Olúwa Ọ̀gá-ògo ti ní ẹ̀rù tó
ọba ńlá lórí gbogbo ayé. 3Ṣe ìkápá àwọn orílẹ̀-èdè lábẹ́ wa
àwọn ènìyàn lábẹ́ ẹsẹ̀ wa 4Ó mú ilẹ̀ ìní wa fún wa,
ọlá Jakọbu, ẹni tí ó fẹ́ wa. 5Ọlọ́run tó gòkè lọ tí òun tayọ̀,
Olúwa ti òun ti ariwo ìpè. 6Ẹ kọrin ìyìn sí Ọlọ́run, ẹ kọrin ìyìn.
Ẹ kọrin ìyìn sí ọba wa, ẹ kọrin ìyìn! 7Nítorí Ọlọ́run ni ọba gbogbo ayé,
ẹ kọrin ìyìn pẹ̀lú Saamu! 8Ọlọ́run jẹ ọba lórí gbogbo kèfèrí;
Ọlọ́run jókòó lórí ìtẹ́ ìwà mímọ́ rẹ̀. 9Àwọn aládé ayé kó ara wọn jọ
gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Ọlọ́run Abrahamu
nítorí asà ayé ti Ọlọ́run ni,
òun ni ó ga jùlọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.