Saamu 4:3
Psalms 4:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n kí ẹ mọ̀ pé, Olúwa ti ya ẹni olódodo sọ́tọ̀ fún ara rẹ̀; Olúwa yóò gbọ́ nígbà tí mo bá pè é.
Psalms 4:3 in English
Psalms 4:3 · Berean Standard Bible
Know that the LORD has set apart the godly for Himself; the LORD hears when I call to Him.
Context
1Dá mi lóhùn nígbà tí mo bá pè ọ́,
ìwọ Ọlọ́run òdodo mi.
Fún mi ní ìdáǹdè nínú ìpọ́njú mi;
ṣàánú fún mi, kí o sì gbọ́ àdúrà mi. 2Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó, ẹ̀yin ọmọ ènìyàn, tí ẹ ó ṣe sọ ògo mi di ìtìjú?
Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó, tí ẹ̀yin yóò ṣe fẹ́ràn ìtànjẹ àti tí ẹ̀yin yóò fi máa wá ọlọ́run èké? 3Ṣùgbọ́n kí ẹ mọ̀ pé, Olúwa ti ya ẹni olódodo sọ́tọ̀ fún ara rẹ̀;
Olúwa yóò gbọ́ nígbà tí mo bá pè é. 4Ẹ bínú ẹ má ṣe ṣẹ̀,
nígbà tí ẹ bá wà lórí ibùsùn yín,
ẹ bá ọkàn yín sọ̀rọ̀, kí ó sì dákẹ́ jẹ́. 5Ẹ rú ẹbọ òdodo
kí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.