Saamu 4:1
Psalms 4:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Dá mi lóhùn nígbà tí mo bá pè ọ́, ìwọ Ọlọ́run òdodo mi. Fún mi ní ìdáǹdè nínú ìpọ́njú mi; ṣàánú fún mi, kí o sì gbọ́ àdúrà mi.
Psalms 4:1 in English
Psalms 4:1 · Berean Standard Bible
Answer me when I call, O God of my righteousness! You have relieved my distress; show me grace and hear my prayer.
Context
1Dá mi lóhùn nígbà tí mo bá pè ọ́,
ìwọ Ọlọ́run òdodo mi.
Fún mi ní ìdáǹdè nínú ìpọ́njú mi;
ṣàánú fún mi, kí o sì gbọ́ àdúrà mi. 2Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó, ẹ̀yin ọmọ ènìyàn, tí ẹ ó ṣe sọ ògo mi di ìtìjú?
Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó, tí ẹ̀yin yóò ṣe fẹ́ràn ìtànjẹ àti tí ẹ̀yin yóò fi máa wá ọlọ́run èké? 3Ṣùgbọ́n kí ẹ mọ̀ pé, Olúwa ti ya ẹni olódodo sọ́tọ̀ fún ara rẹ̀;
Olúwa yóò gbọ́ nígbà tí mo bá pè é.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.