Saamu 38:5
Psalms 38:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọgbẹ́ mi ń rùn ó sì díbàjẹ́ nítorí òmùgọ̀ mi.
Psalms 38:5 in English
Psalms 38:5 · Berean Standard Bible
My wounds are foul and festering because of my sinful folly.
Context
3Kò sí ibi yíyè ní ara à mi, nítorí ìbínú rẹ;
kò sí àlàáfíà nínú egungun mi nítorí i ẹ̀ṣẹ̀ mi. 4Nítorí àìṣedéédéé mi ti borí mi mọ́lẹ̀;
wọ́n tó ìwọ̀n bi àjàgà tí ó wúwo jù fún mi. 5Ọgbẹ́ mi ń rùn ó sì díbàjẹ́
nítorí òmùgọ̀ mi. 6Èmi ń jòwèrè, orí mi tẹ̀ ba gidigidi
èmi ń ṣọ̀fọ̀ rìn kiri ní gbogbo ọjọ́. 7Nítorí ẹ̀gbẹ́ mi kún fún ìgbóná tí ń jóni
kò sì ṣí ibi yíyè ní ara mi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.