Native Bible

Psalms 37:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, kí o sì máa ṣe rere; torí pé ìwọ yóò gbé ilẹ̀ náà, kí o sì gbádùn ààbò rẹ̀.

Psalms 37:3 in English

Psalms 37:3 · Berean Standard Bible

Trust in the LORD and do good; dwell in the land and cultivate faithfulness.

Context

1Má ṣe ìkanra nítorí àwọn olùṣe búburú, kí ìwọ má sì ṣe ṣe ìlara nítorí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀; 2nítorí pé wọn yóò gbẹ bí i koríko, wọn yóò sì rẹ̀ dànù bí ewéko tútù. 3Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, kí o sì máa ṣe rere; torí pé ìwọ yóò gbé ilẹ̀ náà, kí o sì gbádùn ààbò rẹ̀. 4Ṣe inú dídùn sí Olúwa; òun yóò sì fún ọ ní ìfẹ́ inú rẹ̀. 5Fi ọ̀nà rẹ lé Olúwa lọ́wọ́; gbẹ́kẹ̀lé pẹ̀lú, òun yóò sì ṣe é.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.