Native Bible

Psalms 36:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí pé pẹ̀lú rẹ ni orísun ìyè wà: nínú ìmọ́lẹ̀ rẹ ni àwa yóò rí ìmọ́lẹ̀.

Psalms 36:9 in English

Psalms 36:9 · Berean Standard Bible

For with You is the fountain of life; in Your light we see light.

Context

7Báwo ni ìṣeun ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ ti tó! Ọlọ́run! Kí gbogbo ọmọ ènìyàn le sá sí abẹ́ òjìji ìyẹ́ rẹ. 8Àsè ilé rẹ yóò tẹ́ wọn lọ́rùn gidigidi; ìwọ yóò sì mú wọn mu nínú odò inú dídùn rẹ. 9Nítorí pé pẹ̀lú rẹ ni orísun ìyè wà: nínú ìmọ́lẹ̀ rẹ ni àwa yóò rí ìmọ́lẹ̀. 10Mú ìṣeun ìfẹ́ ẹ̀ rẹ sí àwọn tí ó mọ̀ ọ́n àti ìgbàlà rẹ sí àwọn tí ó ní ìdúró ṣinṣin ọkàn! 11Má ṣe jẹ́ kí ẹsẹ̀ agbéraga kí ó wá sí orí mi, kí o má sì jẹ́ kí ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú sí mi ní ipò.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.