Saamu 36:4
Psalms 36:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n gbìmọ̀ ìwà ìkà nígbà tí wọ́n wà lórí ibùsùn wọn: wọ́n gba ọ̀nà tí kò dára wọn kò sì kọ ọ̀nà ibi sílẹ̀.
Psalms 36:4 in English
Psalms 36:4 · Berean Standard Bible
Even on his bed he plots wickedness; he sets himself on a path that is not good; he fails to reject evil.
Context
2Nítorí pé wọ́n pọ́n ara wọn ní ojú ara wọn
títí tí a kò fi le rí ẹ̀ṣẹ̀ wọn láti kórìíra. 3Ọ̀rọ̀ ẹnu wọn ni ẹ̀ṣẹ̀ òhun ẹ̀tàn;
wọ́n ti fi ọgbọ́n àti ṣíṣe rere sílẹ̀. 4Wọ́n gbìmọ̀ ìwà ìkà nígbà tí wọ́n wà lórí ibùsùn wọn:
wọ́n gba ọ̀nà tí kò dára
wọn kò sì kọ ọ̀nà ibi sílẹ̀. 5Ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ, ìwọ Olúwa, ó ga dé ọ̀run,
òtítọ́ ọ̀ rẹ ga dé àwọsánmọ̀. 6Òdodo rẹ dàbí àwọn òkè Ọlọ́run,
àwọn ìdájọ́ rẹ dàbí ibú ńlá;
ìwọ gba ẹranko àti ènìyàn là, Olúwa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.