Saamu 35:20
Psalms 35:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí pé wọn kò sọ ọ̀rọ̀ àlàáfíà, ṣùgbọ́n wọ́n lóyún ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn sí àwọn ènìyàn dídákẹ́ ilẹ̀ náà.
Psalms 35:20 in English
Psalms 35:20 · Berean Standard Bible
For they do not speak peace, but they devise deceitful schemes against those who live quietly in the land.
Context
18Nígbà náà ni èmi yóò ṣọpẹ́ fún Ọ nínú àjọ ńlá;
èmi yóò máa yìn Ọ́ ní àwùjọ ọ̀pọ̀ ènìyàn. 19Má ṣe jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi
kí ó yọ̀ lórí ì mi;
bẹ́ẹ̀ ni kí o má ṣe àwọn tí ó kórìíra mi
ní àìnídìí máa ṣẹ́jú sí mi. 20Nítorí pé wọn kò sọ ọ̀rọ̀ àlàáfíà,
ṣùgbọ́n wọ́n lóyún ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn
sí àwọn ènìyàn dídákẹ́ ilẹ̀ náà. 21Wọ́n ya ẹnu wọn gbòòrò sí mi; wọ́n wí pé, “Háà! Háà!
Ojú wa sì ti rí i.” 22Ìwọ́ ti rí i Olúwa; má ṣe dákẹ́!
Olúwa má ṣe jìnnà sí mi!
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.