Native Bible

Psalms 34:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gbé Olúwa ga pẹ̀lú mi; kí ẹ sì jẹ́ kí a jọ gbé orúkọ rẹ̀ lékè.

Psalms 34:3 in English

Psalms 34:3 · Berean Standard Bible

Magnify the LORD with me; let us exalt His name together.

Context

1Èmi yóò máa fi ìbùkún fún Olúwa nígbà gbogbo; ìyìn rẹ̀ yóò máa wà ní ẹnu mi títí láé. 2Ọkàn mí yóò máa ṣògo nínú Olúwa; jẹ́ kí àwọn onírẹ̀lẹ̀ gbọ́ kí inú wọn kí ó sì máa dùn. 3Gbé Olúwa ga pẹ̀lú mi; kí ẹ sì jẹ́ kí a jọ gbé orúkọ rẹ̀ lékè. 4Èmi wá Olúwa, ó sì dá mi lóhùn; Ó sì gbà mí kúrò nínú ìbẹ̀rù mi gbogbo. 5Wọ́n wò ó, ìmọ́lẹ̀ sì mọ́ wọn; ojú kò sì tì wọ́n.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.