Native Bible

Psalms 33:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olúwa ti mú ìmọ̀ràn àwọn orílẹ̀-èdè wá sí asán; ó sì mú àrékérekè àwọn ènìyàn di ṣíṣákì í.

Psalms 33:10 in English

Psalms 33:10 · Berean Standard Bible

The LORD frustrates the plans of the nations; He thwarts the devices of the peoples.

Context

8Jẹ́ kí gbogbo ayé kí ó bẹ̀rù Olúwa: jẹ́ kí gbogbo àwọn olùgbé ayé kí ó wà nínú ìbẹ̀rù rẹ̀. 9Nítorí tí ó sọ̀rọ̀, ó sì ti rí bẹ́ẹ̀; ó pàṣẹ ó sì dúró ṣinṣin. 10Olúwa ti mú ìmọ̀ràn àwọn orílẹ̀-èdè wá sí asán; ó sì mú àrékérekè àwọn ènìyàn di ṣíṣákì í. 11Ìgbìmọ̀ Olúwa dúró títí ayérayé, àní ìrò inú rẹ̀ láti ìrandíran ni. 12Ìbùkún ni fún orílẹ̀-èdè náà, Ọlọ́run ẹni tí Olúwa jẹ́ tirẹ̀, àti àwọn ènìyàn náà tí ó ti yàn ṣe ìní rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.