Native Bible

Psalms 32:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí mo dákẹ́, egungun mi di gbígbó dànù nípa ìkérora mi ní gbogbo ọjọ́.

Psalms 32:3 in English

Psalms 32:3 · Berean Standard Bible

When I kept silent, my bones became brittle from my groaning all day long.

Context

1Ìbùkún ni fún àwọn tí a dárí ìrékọjá wọn jì, tí a sì bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀. 2Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà ẹni tí Olúwa kò ka ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ sí i lọ́rùn àti nínú ẹ̀mí ẹni tí kò sí ẹ̀tàn. 3Nígbà tí mo dákẹ́, egungun mi di gbígbó dànù nípa ìkérora mi ní gbogbo ọjọ́. 4Nítorí pé ni ọ̀sán àti ní òru ọwọ́ rẹ̀ wúwo sí mi lára; agbára mi gbẹ tán gẹ́gẹ́ bí ooru ẹ̀ẹ̀rùn. Sela. 5Èmi jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ọ àti pé èmi kò sì fi àìṣòdodo mi pamọ́. Èmi wí pé, “Èmi yóò jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi fún Olúwa,” ìwọ sì dárí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí. Sela.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.