Native Bible

Psalms 31:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣàánú fún mi, ìwọ Olúwa, nítorí mo wà nínú ìpọ́njú; ojú mi fi ìbìnújẹ́ sùn, ọkàn àti ara mi pẹ̀lú.

Psalms 31:9 in English

Psalms 31:9 · Berean Standard Bible

Be merciful to me, O LORD, for I am in distress; my eyes fail from sorrow, my soul and body as well.

Context

7Èmi yóò yọ̀, inú mi yóò dùn nínú ìfẹ́ ńlá rẹ, nítorí ìwọ ti rí ìbìnújẹ́ mi ìwọ ti mọ̀ ọkàn mi nínú ìpọ́njú. 8Pẹ̀lú, ìwọ kò sì fà mi lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́ ìwọ ti fi ẹsẹ̀ mi lé ibi ààyè ńlá. 9Ṣàánú fún mi, ìwọ Olúwa, nítorí mo wà nínú ìpọ́njú; ojú mi fi ìbìnújẹ́ sùn, ọkàn àti ara mi pẹ̀lú. 10Èmi fi ìbànújẹ́ lo ọjọ́ mi àti àwọn ọdún mi pẹ̀lú ìmí ẹ̀dùn; agbára mi ti kùnà nítorí òsì mi, egungun mi sì ti rún dànù. 11Èmi di ẹni ẹ̀gàn láàrín àwọn ọ̀tá mi gbogbo, pẹ̀lúpẹ̀lú láàrín àwọn aládùúgbò mi, mo sì di ẹ̀rù fún àwọn ojúlùmọ̀ mi; àwọn tí ó rí mi ní òde ń yẹra fún mi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.