Native Bible

Psalms 31:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi fi ìbànújẹ́ lo ọjọ́ mi àti àwọn ọdún mi pẹ̀lú ìmí ẹ̀dùn; agbára mi ti kùnà nítorí òsì mi, egungun mi sì ti rún dànù.

Psalms 31:10 in English

Psalms 31:10 · Berean Standard Bible

For my life is consumed with grief and my years with groaning; my iniquity has drained my strength, and my bones are wasting away.

Context

8Pẹ̀lú, ìwọ kò sì fà mi lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́ ìwọ ti fi ẹsẹ̀ mi lé ibi ààyè ńlá. 9Ṣàánú fún mi, ìwọ Olúwa, nítorí mo wà nínú ìpọ́njú; ojú mi fi ìbìnújẹ́ sùn, ọkàn àti ara mi pẹ̀lú. 10Èmi fi ìbànújẹ́ lo ọjọ́ mi àti àwọn ọdún mi pẹ̀lú ìmí ẹ̀dùn; agbára mi ti kùnà nítorí òsì mi, egungun mi sì ti rún dànù. 11Èmi di ẹni ẹ̀gàn láàrín àwọn ọ̀tá mi gbogbo, pẹ̀lúpẹ̀lú láàrín àwọn aládùúgbò mi, mo sì di ẹ̀rù fún àwọn ojúlùmọ̀ mi; àwọn tí ó rí mi ní òde ń yẹra fún mi. 12Èmi ti di ẹni ìgbàgbé kúrò ní ọkàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ti kú; èmi sì dàbí ohun èlò tí ó ti fọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.