Saamu 31:16
Psalms 31:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí ìránṣẹ́ rẹ lára; gbà mí nínú ìfẹ́ rẹ tí ó dúró ṣinṣin.
Psalms 31:16 in English
Psalms 31:16 · Berean Standard Bible
Make Your face shine on Your servant; save me by Your loving devotion.
Context
14Ṣùgbọ́n èmí gbẹ́kẹ̀lé ọ, ìwọ Olúwa;
mo sọ wí pé, “Ìwọ ní Ọlọ́run mi.” 15Ìgbà mi ń bẹ ní ọwọ́ rẹ;
gbà mí kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá mi
àti àwọn onínúnibíni. 16Jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí ìránṣẹ́ rẹ lára;
gbà mí nínú ìfẹ́ rẹ tí ó dúró ṣinṣin. 17Má ṣe jẹ́ kí ojú ki ó tì mí, Olúwa;
nítorí pé mo ké pè ọ́;
jẹ́ kí ojú kí ó ti ènìyàn búburú;
jẹ́ kí wọ́n lọ pẹ̀lú ìdààmú sí isà òkú. 18Jẹ́ kí àwọn ètè irọ́ kí ó dákẹ́ jẹ́ẹ́,
pẹ̀lú ìgbéraga àti ìkẹ́gàn,
wọ́n sọ̀rọ̀ àfojúdi sí olódodo.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.