Native Bible

Psalms 25:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹni tí ó dúró tì ọ́ ojú kì yóò tì í, àwọn tí ń ṣẹ̀ láìnídìí ni kí ojú kí ó tì.

Psalms 25:3 in English

Psalms 25:3 · Berean Standard Bible

Surely none who wait for You will be put to shame; but those who are faithless without cause will be disgraced.

Context

1Olúwa, ìwọ ni mo gbé ọkàn mi sókè sí. 2Ọlọ́run, èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ; má ṣe jẹ́ kí ojú ó tì mí má ṣe jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi ó yọ̀ mí. 3Ẹni tí ó dúró tì ọ́ ojú kì yóò tì í, àwọn tí ń ṣẹ̀ láìnídìí ni kí ojú kí ó tì. 4Fi ọ̀nà rẹ hàn mí, Olúwa, kọ mi ní ipa tìrẹ; 5ṣe amọ̀nà mi nínú òtítọ́ ọ̀ rẹ, kí o sì kọ́ mi, nítorí ìwọ ni Ọlọ́run ìgbàlà mi; ìwọ ni mo dúró tì ní gbogbo ọjọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.