Saamu 22:28
Psalms 22:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
nítorí ìjọba ni ti Olúwa. Òun ni ó ń pàṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè.
Psalms 22:28 in English
Psalms 22:28 · Berean Standard Bible
For dominion belongs to the LORD and He rules over the nations.
Context
26tálákà yóò jẹ yóò sì yó;
àwọn tí n wá Olúwa yóò yin
jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ̀ wà láààyè títí ayérayé! 27Gbogbo òpin ayé ni yóò rántí
wọn yóò sì yípadà sí Olúwa,
àti gbogbo ìdílé orílẹ̀-èdè
ni wọn yóò jọ́sìn níwájú rẹ̀, 28nítorí ìjọba ni ti Olúwa.
Òun ni ó ń pàṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè. 29Bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo àwọn olówó ayé wọn yóò ṣe àsè, wọn yóò sì sìn;
gbogbo àwọn tí ó wọ inú ilẹ̀ lọ yóò kúnlẹ̀ ní iwájú rẹ̀
àti ẹni tí kò lè pa ọkàn ara rẹ̀ mọ́ ni ààyè. 30Irú-ọmọ rẹ̀ yóò sìn ín;
a ó sọ fún àwọn ìran tí ń bọ̀ nípa Olúwa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.