Saamu 22:16
Psalms 22:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ajá yí mi ká; ìjọ àwọn ènìyàn ibi ti ká mi mọ́, wọ́n gún mi lọ́wọ́, wọ́n sì gún mi lẹ́sẹ̀.
Psalms 22:16 in English
Psalms 22:16 · Berean Standard Bible
For dogs surround me; a band of evil men encircles me; they have pierced my hands and feet.*
Context
14A dà mí jáde gẹ́gẹ́ bí omi,
gbogbo egungun mi ti yẹ̀ kúrò ní oríkèé rẹ̀.
Ọkàn mi sì dàbí i ìda;
tí ó yọ́ láàrín inú mi. 15Agbára mí ti gbẹ bí àpáàdì,
ahọ́n mí sì tilẹ̀ mọ́ párí ẹ̀rẹ̀kẹ́ ẹ mi;
ìwọ ti tẹ́ mi sínú eruku ikú. 16Àwọn ajá yí mi ká;
ìjọ àwọn ènìyàn ibi ti ká mi mọ́,
wọ́n gún mi lọ́wọ́, wọ́n sì gún mi lẹ́sẹ̀. 17Mo lè ka gbogbo àwọn egungun mi;
àwọn tìkára wọn ń wò, wọ́n dójú lé mi. 18Wọ́n pín aṣọ mi láàrín ara wọn
àní lórí aṣọ mi ni wọ́n ṣẹ́ gègé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.