Saamu 22:13
Psalms 22:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n ya ẹnu wọn sì mi bí i kìnnìún tí ń dọdẹ kiri, tí ń ké ramúramù.
Psalms 22:13 in English
Psalms 22:13 · Berean Standard Bible
They open their jaws against me like lions that roar and maul.
Context
11Má ṣe jìnnà sí mi,
nítorí pé ìyọnu súnmọ́ tòsí
kò sì ṣí ẹnìkan tí yóò ṣe ìrànlọ́wọ́. 12Ọ̀pọ̀ akọ màlúù yí mi ká;
àwọn màlúù alágbára Baṣani rọ̀gbà yí mi ká. 13Wọ́n ya ẹnu wọn sì mi bí i kìnnìún tí ń dọdẹ kiri,
tí ń ké ramúramù. 14A dà mí jáde gẹ́gẹ́ bí omi,
gbogbo egungun mi ti yẹ̀ kúrò ní oríkèé rẹ̀.
Ọkàn mi sì dàbí i ìda;
tí ó yọ́ láàrín inú mi. 15Agbára mí ti gbẹ bí àpáàdì,
ahọ́n mí sì tilẹ̀ mọ́ párí ẹ̀rẹ̀kẹ́ ẹ mi;
ìwọ ti tẹ́ mi sínú eruku ikú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.