Native Bible

Psalms 20:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kí ó sì rántí gbogbo ẹbọ rẹ kí ó sì gba ẹbọ sísun rẹ. Sela.

Psalms 20:3 in English

Psalms 20:3 · Berean Standard Bible

May He remember all your gifts and look favorably on your burnt offerings. Selah

Context

1Kí Olúwa kí ó gbóhùn rẹ ní ọjọ́ ìpọ́njú; kí orúkọ Ọlọ́run Jakọbu kí ó dáàbò bò ọ́. 2Kí ó rán ìrànlọ́wọ́ sí ọ, láti ibi mímọ́ kí ó sì tì ọ́ lẹ́yìn láti Sioni wá. 3Kí ó sì rántí gbogbo ẹbọ rẹ kí ó sì gba ẹbọ sísun rẹ. Sela. 4Kí ó fi fún ọ gẹ́gẹ́ bi ti èrò ọkàn rẹ kí ó sì mú gbogbo ìmọ̀ rẹ ṣẹ. 5Àwa yóò hó fún ayọ̀ nígbà tí o bá di aṣẹ́gun àwa yóò gbé àsíá wa sókè ní orúkọ Ọlọ́run wa. Kí Olúwa kí ó mú gbogbo ìbéèrè rẹ̀ ṣẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.