Native Bible

Psalms 18:43 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìwọ ti gbà mí lọ́wọ́ ìkọlù àwọn ènìyàn; Ìwọ ti fi mí ṣe olórí àwọn orílẹ̀-èdè. Àwọn ènìyàn ti èmi kò mọ, yóò sì máa sìn mí,

Psalms 18:43 in English

Psalms 18:43 · Berean Standard Bible

You have delivered me from the strife of the people; You have made me the head of nations; a people I had not known shall serve me.

Context

41Wọ́n kígbe fún ìrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó gbà wọ́n, àní sí Olúwa, ṣùgbọ́n kò dá wọn lóhùn. 42Mo lù wọ́n gẹ́gẹ́ bí eruku níwájú afẹ́fẹ́; mo dà wọ́n síta gẹ́gẹ́ bí ẹrọ̀fọ̀. 43Ìwọ ti gbà mí lọ́wọ́ ìkọlù àwọn ènìyàn; Ìwọ ti fi mí ṣe olórí àwọn orílẹ̀-èdè. Àwọn ènìyàn ti èmi kò mọ, yóò sì máa sìn mí, 44ni wéré ti wọ́n gbọ́ ohùn mi, wọ́n pa àṣẹ mi mọ́; àwọn ọmọ àjèjì yóò tẹríba fún mi. 45Àyà yóò pá àlejò; wọn yóò sì fi ìbẹ̀rù jáde láti ibi kọ́lọ́fín wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.