Saamu 18:39
Psalms 18:39 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí ìwọ fi agbára dì mí ní àmùrè fún ogun náà; ìwọ ti mú àwọn tí ó dìde si mí tẹríba ní abẹ́ ẹsẹ̀ mi.
Psalms 18:39 in English
Psalms 18:39 · Berean Standard Bible
You have armed me with strength for battle; You have subdued my foes beneath me.
Context
37Èmi lépa àwọn ọ̀tá mi, èmi sì bá wọn
èmi kò sì padà lẹ́yìn wọn títí a fi run wọ́n. 38Èmi sá wọn ní ọgbẹ́ tí wọn ko fi le è dìde;
wọ́n ṣubú ní abẹ́ ẹsẹ̀ mi. 39Nítorí ìwọ fi agbára dì mí ní àmùrè fún ogun náà;
ìwọ ti mú àwọn tí ó dìde si mí tẹríba ní abẹ́ ẹsẹ̀ mi. 40Ìwọ yí ẹ̀yìn àwọn ọ̀tá mí padà sí mi
èmi sì pa àwọn tí ó kórìíra mi run. 41Wọ́n kígbe fún ìrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó gbà wọ́n,
àní sí Olúwa, ṣùgbọ́n kò dá wọn lóhùn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.