Native Bible

Psalms 18:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó gun orí kérúbù, ó sì fò; ó ń rábàbà lórí ìyẹ́ apá afẹ́fẹ́.

Psalms 18:10 in English

Psalms 18:10 · Berean Standard Bible

He mounted a cherub and flew; He soared on the wings of the wind.

Context

8Èéfín ti ihò imú rẹ̀ jáde wá; iná ajónirun ti ẹnu rẹ̀ jáde wá, ẹ̀yin iná bú jáde láti inú rẹ̀. 9Ó pín àwọn ọ̀run, Ó sì jáde wá; àwọsánmọ̀ dúdú sì wà ní abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀. 10Ó gun orí kérúbù, ó sì fò; ó ń rábàbà lórí ìyẹ́ apá afẹ́fẹ́. 11Ó fi òkùnkùn ṣe ibojì rẹ̀, ó fi ṣe ìbòrí yí ara rẹ̀ ká kurukuru òjò dúdú ní ojú ọ̀run. 12Nípa ìmọ́lẹ̀ iwájú rẹ̀, àwọsánmọ̀ ṣíṣú dudu rẹ kọjá lọ pẹ̀lú yìnyín àti ẹ̀yín iná

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.