Saamu 16:6
Psalms 16:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Okùn ààlà ilẹ̀ ti bọ́ sí ọ̀dọ̀ mi ní ibi dídára; nítòótọ́ mo ti ní ogún rere.
Psalms 16:6 in English
Psalms 16:6 · Berean Standard Bible
The lines of my boundary have fallen in pleasant places; surely my inheritance is delightful.
Context
4Ìṣòro àwọn wọ̀n-ọn-nì yóò pọ̀ sí i, àní àwọn tí ń tọ ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn.
Ẹbọ ohun mímu ẹ̀jẹ̀ wọn ni èmi kì yóò ta sílẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò dá orúkọ wọn lẹ́nu mi. 5Olúwa, ni ìpín ìní mi tí mo yàn àti ago mi,
ó ti pa ohun tí í ṣe tèmi mọ́. 6Okùn ààlà ilẹ̀ ti bọ́ sí ọ̀dọ̀ mi ní ibi dídára;
nítòótọ́ mo ti ní ogún rere. 7Èmi yóò yin Olúwa, ẹni tí ó gbà mí ní ìyànjú;
ní òru, ọkàn mí ń bá mi sọ̀rọ̀. 8Mo ti gbé Olúwa síwájú mi ní ìgbà gbogbo.
Nítorí tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi, a kì yóò mì mí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.