Native Bible

Psalms 139:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítòótọ́ òkùnkùn kì í ṣú lọ́dọ̀ rẹ; ṣùgbọ́n òru tan ìmọ́lẹ̀ bí ọ̀sán; àti òkùnkùn àti ọ̀sán, méjèèjì bákan náà ní fún ọ.

Psalms 139:12 in English

Psalms 139:12 · Berean Standard Bible

even the darkness is not dark to You, but the night shines like the day, for darkness is as light to You.

Context

10àní, níbẹ̀ náà ni ọwọ́ rẹ̀ yóò fà mí ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì dì mímú. 11Bí mo bá wí pé, “Ǹjẹ́ kí òkùnkùn kí ó bò mí mọ́lẹ̀; kí ìmọ́lẹ̀ kí ó di òru yí mi ká.” 12Nítòótọ́ òkùnkùn kì í ṣú lọ́dọ̀ rẹ; ṣùgbọ́n òru tan ìmọ́lẹ̀ bí ọ̀sán; àti òkùnkùn àti ọ̀sán, méjèèjì bákan náà ní fún ọ. 13Nítorí ìwọ ni ó dá ọkàn mi; ìwọ ni ó bò mí mọ́lẹ̀ nínú ìyá mi. 14Èmi yóò yìn ọ, nítorí tẹ̀rù tẹ̀rù àti tìyanu tìyanu ní a dá mi; ìyanu ní iṣẹ́ rẹ; èyí nì ni ọkàn mi sì mọ̀ dájúdájú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.