Native Bible

Psalms 12:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

tí ó wí pé, “Àwa ó borí pẹ̀lú ahọ́n wa; àwa ní ètè wa, ta ni ọ̀gá wa?”

Psalms 12:4 in English

Psalms 12:4 · Berean Standard Bible

They say, “With our tongues we will prevail. We own our lips—who can be our master?”

Context

2Olúkúlùkù ń parọ́ fún aládùúgbò rẹ̀; ètè èké wọn ń sọ ẹ̀tàn. 3Kí Olúwa kí ó gé ètè èké wọn àti gbogbo ahọ́n ìfọ́nnu 4tí ó wí pé, “Àwa ó borí pẹ̀lú ahọ́n wa; àwa ní ètè wa, ta ni ọ̀gá wa?” 5“Nítorí ìnilára àwọn aláìlágbára àti ìkérora àwọn aláìní, Èmi yóò dìde nísinsin yìí,” ni Olúwa wí. “Èmi yóò dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn tí ń ṣe àrankàn wọn.” 6Ọ̀rọ̀ Olúwa sì jẹ aláìlábùkù, gẹ́gẹ́ bí fàdákà tí a yọ́ nínú ìléru amọ̀, tí a sọ di mímọ́ nígbà méje.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.