Native Bible

Psalms 119:81 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọkàn mi ń fojú ṣọ́nà nítorí ìgbàlà rẹ, ṣùgbọ́n èmi ti fi ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.

Psalms 119:81 in English

Psalms 119:81 · Berean Standard Bible

My soul faints for Your salvation; I wait for Your word.

Context

79Kí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ yí padà sí mi, àwọn tí ó ní òye òfin rẹ. 80Jẹ́ kí ọkàn mi wà láìlẹ́bi sí òfin rẹ, kí ojú kí ó má ṣe tì mí. 81Ọkàn mi ń fojú ṣọ́nà nítorí ìgbàlà rẹ, ṣùgbọ́n èmi ti fi ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ. 82Ojú mi kùnà, pẹ̀lú wíwo ìpinnu rẹ; èmi wí pé, “Nígbà wo ni ìwọ yóò tù mí nínú?” 83Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi dàbí awọ-wáìnì lójú èéfín, èmi kò gbàgbé ìlànà rẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.