Native Bible

Psalms 116:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olúwa ní oore-ọ̀fẹ́, ó sì ní òdodo; Ọlọ́run wa kún fún àánú.

Psalms 116:5 in English

Psalms 116:5 · Berean Standard Bible

The LORD is gracious and righteous; our God is full of compassion.

Context

3Okùn ikú yí mi ká, ìrora isà òkú wá sórí mi; ìyọnu àti ìbànújẹ́ borí mi. 4Nígbà náà ni mo ké pe orúkọ Olúwa: “Olúwa, èmi bẹ̀ ọ́, gba ọkàn mi!” 5Olúwa ní oore-ọ̀fẹ́, ó sì ní òdodo; Ọlọ́run wa kún fún àánú. 6Olúwa pa àwọn ọlọ́kàn fífúyẹ́ mọ́ nígbà tí mo wà nínú àìní ńlá, ó gbà mí. 7Padà, ìwọ ọkàn mi, sí ibi ìsinmi rẹ, nítorí Olúwa ṣe dáradára sí ọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.