Native Bible

Psalms 11:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí ìpìlẹ̀ bá bàjẹ́ kí ni olódodo yóò ṣe?”

Psalms 11:3 in English

Psalms 11:3 · Berean Standard Bible

If the foundations are destroyed, what can the righteous do?”

Context

1Ìgbẹ́kẹ̀lé mi wà nínú Olúwa. Báwo ní ẹ̀yin ó ṣe sọ fún ọkàn mi pé, “Fò gẹ́gẹ́ bi ẹyẹ lọ si orí òkè rẹ. 2Wò ó nítorí náà, ènìyàn búburú fa ọfà rẹ̀; wọn ti fi ọfà wọn sí ojú okùn láti tafà níbi òjìji sí àyà ẹni ìdúró ṣinṣin. 3Nígbà tí ìpìlẹ̀ bá bàjẹ́ kí ni olódodo yóò ṣe?” 4Olúwa ń bẹ nínú tẹmpili mímọ́ rẹ̀; Olúwa ń bẹ lórí ìtẹ́ rẹ̀ ní ọ̀run. Ó ń wo àwọn ọmọ ènìyàn; ojú rẹ̀ ń yẹ̀ wọ́n wò. 5Olúwa ń yẹ olódodo wò, ṣùgbọ́n ènìyàn búburú àti àwọn tí o fẹ́ ìwà ipá ni ọkàn rẹ̀ kórìíra.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.