Saamu 108:8
Psalms 108:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gileadi ni tèmi, Manase ni tèmi, Efraimu ni ìbòrí mi, Juda ni olófin mi,
Psalms 108:8 in English
Psalms 108:8 · Berean Standard Bible
Gilead is Mine, and Manasseh is Mine; Ephraim is My helmet, Judah is My scepter.
Context
6Kí a sì lè gba àwọn olùfẹ́ rẹ là;
fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ ṣe ìgbàlà,
kí o sì dá mi lóhùn 7Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ láti ibi mímọ́ rẹ̀ pé,
“Èmi yóò yọ̀, èmi yóò pín Ṣekemu,
èmi yóò sì wọn àfonífojì Sukkoti kúrò. 8Gileadi ni tèmi, Manase ni tèmi,
Efraimu ni ìbòrí mi,
Juda ni olófin mi, 9Moabu sì ni ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi,
lórí Edomu ni èmi ó bọ́ bàtà mi sí,
lórí òkè Filistia ni èmi yóò hó ìhó ayọ̀.” 10Ta ni yóò mú mi wá sí ìlú olódi?
Ta ni yóò sìn mí wá sí Edomu?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.