Saamu 107:3
Psalms 107:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
àwọn tí ó kójọ láti ilẹ̀ wọ̀n-ọn-nì, láti ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn, láti àríwá àti Òkun wá.
Psalms 107:3 in English
Psalms 107:3 · Berean Standard Bible
and gathered from the lands, from east and west, from north and south.*
Context
1Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó ṣeun;
nítorí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé. 2Jẹ́ kí àwọn ẹni ìràpadà Olúwa kí ó wí báyìí,
àwọn ẹni tí ó rà padà kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá, 3àwọn tí ó kójọ láti ilẹ̀ wọ̀n-ọn-nì,
láti ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn,
láti àríwá àti Òkun wá. 4Wọ́n ń rìn káàkiri ní aginjù ní ibi tí ọ̀nà kò sí,
wọn kò rí ọ̀nà lọ sí ìlú níbi tí
wọn ó máa gbé. 5Ebi ń pa wọn, òǹgbẹ gbẹ wọ́n,
ó sì rẹ ọkàn wọn nínú wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.