Native Bible

Psalms 104:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìwọ mú òkùnkùn wá, ó sì di òru, nínú èyí tí gbogbo ẹranko igbó ń rìn kiri.

Psalms 104:20 in English

Psalms 104:20 · Berean Standard Bible

You bring darkness, and it becomes night, when all the beasts of the forest prowl.

Context

18Àwọn òkè gíga ni ààbò fún àwọn ewúrẹ́ igbó; àti àwọn àlàpà jẹ́ ààbò fún àwọn ehoro. 19Òṣùpá jẹ́ àmì fún àkókò oòrùn sì mọ ìgbà tí yóò wọ̀. 20Ìwọ mú òkùnkùn wá, ó sì di òru, nínú èyí tí gbogbo ẹranko igbó ń rìn kiri. 21Kìnnìún ń bú ramúramù fún ohun ọdẹ wọn wọ́n sì ń wá oúnjẹ wọn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. 22Oòrùn ràn, wọ́n sì kó ara wọn jọ, wọn padà lọ dùbúlẹ̀ sí ihò wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.