Native Bible

Psalms 104:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọtí wáìnì tí ó ń mú ọkàn ènìyàn yọ̀, òróró láti mú ojú rẹ̀ tan, àti àkàrà láti ra ọkàn rẹ̀ padà.

Psalms 104:15 in English

Psalms 104:15 · Berean Standard Bible

wine that gladdens the heart of man, oil that makes his face to shine, and bread that sustains his heart.

Context

13Ó bu omi rin àwọn òkè láti ìyẹ̀wù rẹ̀ wá; a tẹ́ ayé lọ́rùn nípa èso iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. 14Ó mú kí koríko hù jáde fún àwọn ẹranko láti jẹ àti àwọn ewébẹ̀ fún ènìyàn láti lò, kí ó lè mú oúnjẹ jáde láti ilẹ̀ wá. 15Ọtí wáìnì tí ó ń mú ọkàn ènìyàn yọ̀, òróró láti mú ojú rẹ̀ tan, àti àkàrà láti ra ọkàn rẹ̀ padà. 16Àwọn igi Olúwa ni a bu omi rin dáradára, kedari ti Lebanoni tí ó gbìn. 17Níbẹ̀ ní àwọn ẹyẹ ṣe ìtẹ́ wọn bí ó ṣe tí àkọ̀ ni, orí igi gíga ni ilé rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.