Native Bible

Psalms 101:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi kì yóò gbé ohun búburú sí iwájú mi: iṣẹ́ àwọn tí ó yapa ni èmi kórìíra. Wọn kì yóò rọ̀ mọ́ mi.

Psalms 101:3 in English

Psalms 101:3 · Berean Standard Bible

I will set no worthless thing before my eyes. I hate the work of those who fall away; it shall not cling to me.

Context

1Èmi yóò kọrin ìfẹ́ àti òdodo; sí ọ Olúwa, èmi yóò máa kọrin ìyìn. 2Èmi yóò máa rin ìrìn mi pẹ̀lú ọgbọ́n láìlẹ́ṣẹ̀, ìgbà wo ni ìwọ yóò wá sí ọ̀dọ̀ mi? Èmi yóò máa rìn ní ilé mi pẹ̀lú àyà pípé. 3Èmi kì yóò gbé ohun búburú sí iwájú mi: iṣẹ́ àwọn tí ó yapa ni èmi kórìíra. Wọn kì yóò rọ̀ mọ́ mi. 4Agídí ọkàn yóò kúrò lọ́dọ̀ mi; èmi kì yóò mọ ènìyàn búburú. 5Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ẹnìkejì rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀, òun ní èmi yóò gé kúrò ẹni tí ó bá gbé ojú rẹ̀ ga tí ó sì ní ìgbéraga àyà, òun ní èmi kì yóò faradà fún.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.