Saamu 10:9
Psalms 10:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó ba ní ní bùba bí i kìnnìún nínú pàǹtí; Ó ba ní bùba láti mú àwọn aláìní ìrànwọ́; ó mú àwọn aláìlólùrànlọ́wọ́, ó sì wọ́ wọn lọ sínú àwọ̀n rẹ̀.
Psalms 10:9 in English
Psalms 10:9 · Berean Standard Bible
He lies in wait like a lion in a thicket; he lurks to seize the oppressed; he catches the lowly in his net.
Context
7Ẹnu rẹ̀ kún fún ègún àti irọ́ àti ìtànjẹ;
wàhálà àti ohun búburú wà lábẹ́ ahọ́n rẹ̀. 8Ó lúgọ ní bùba nítòsí ìletò.
Ò gọ níbi ìkọ̀kọ̀ láti pa aláìṣẹ̀.
Ojú rẹ̀ ń ṣọ́ àwọn tálákà ní ìkọ̀kọ̀. 9Ó ba ní ní bùba bí i kìnnìún nínú pàǹtí;
Ó ba ní bùba láti mú àwọn aláìní ìrànwọ́;
ó mú àwọn aláìlólùrànlọ́wọ́, ó sì wọ́ wọn lọ sínú àwọ̀n rẹ̀. 10Ó ba, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀;
kí tálákà ba à le bọ́ sí ọwọ́ agbára rẹ̀. 11Ó wí fún ara rẹ̀, “Ọlọ́run ti gbàgbé;
Ó pa ojú rẹ̀ mọ́, òun kì yóò rí i láéláé.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.