Saamu 10:3
Psalms 10:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí ènìyàn búburú ń ṣògo ìfẹ́ inú ọkàn rẹ̀; Ó bùkún olójúkòkòrò, ó sì ń kẹ́gàn Olúwa.
Psalms 10:3 in English
Psalms 10:3 · Berean Standard Bible
For the wicked man boasts in the cravings of his heart; he blesses the greedy and reviles the LORD.
Context
1Èéha ti ṣe, Olúwa, tí ìwọ fi dúró ní òkè réré?
Èéha ti ṣe, tí ìwọ fi ara rẹ pamọ́ ní ìgbà ìpọ́njú? 2Nínú àrékérekè ni ènìyàn búburú tí mu aláìlera,
ẹni ti ó mú nínú ìdẹ̀kùn àrékérekè rẹ̀. 3Nítorí ènìyàn búburú ń ṣògo ìfẹ́ inú ọkàn rẹ̀;
Ó bùkún olójúkòkòrò, ó sì ń kẹ́gàn Olúwa. 4Ènìyàn búburú kò lè rí nínú ìgbéraga rẹ̀;
kò sí ààyè fún Ọlọ́run nínú gbogbo èrò rẹ̀. 5Ọ̀nà rẹ̀ ń gún régé nígbà gbogbo;
òun ń gbéraga, òfin rẹ̀ sì jìnnà sí i;
òun kẹ́gàn àwọn ọ̀tá rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.