Saamu 10:4
Psalms 10:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ènìyàn búburú kò lè rí nínú ìgbéraga rẹ̀; kò sí ààyè fún Ọlọ́run nínú gbogbo èrò rẹ̀.
Psalms 10:4 in English
Psalms 10:4 · Berean Standard Bible
In his pride the wicked man does not seek Him; in all his schemes there is no God.
Context
2Nínú àrékérekè ni ènìyàn búburú tí mu aláìlera,
ẹni ti ó mú nínú ìdẹ̀kùn àrékérekè rẹ̀. 3Nítorí ènìyàn búburú ń ṣògo ìfẹ́ inú ọkàn rẹ̀;
Ó bùkún olójúkòkòrò, ó sì ń kẹ́gàn Olúwa. 4Ènìyàn búburú kò lè rí nínú ìgbéraga rẹ̀;
kò sí ààyè fún Ọlọ́run nínú gbogbo èrò rẹ̀. 5Ọ̀nà rẹ̀ ń gún régé nígbà gbogbo;
òun ń gbéraga, òfin rẹ̀ sì jìnnà sí i;
òun kẹ́gàn àwọn ọ̀tá rẹ̀. 6O wí fún ara rẹ̀, “Kò sí ohun tí ó lè mì mí.
Inú mi yóò máa dùn nígbà gbogbo, èmi kò sì ní ní wàhálà.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.