Òwe 7:24
Proverbs 7:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà báyìí ẹ̀yin ọmọ mi, tẹ́tí sí mi fọkàn sí nǹkan tí mo sọ.
Proverbs 7:24 in English
Proverbs 7:24 · Berean Standard Bible
Now, my sons, listen to me, and attend to the words of my mouth.
Context
22Òun sì tọ̀ ọ́ lọ lẹsẹ̀ kan náà,
bí i màlúù tí ń lọ sí ibi pípa,
tàbí bí àgbọ̀nrín tí ń lọ sí ibi okùn ìso. 23Títí tí ọ̀kọ̀ fi gún un ní ẹ̀dọ̀,
bí ẹyẹ ṣe ń fẹ́ wọ inú okùn,
láìmọ̀ pé yóò gba ẹ̀mí òun. 24Nítorí náà báyìí ẹ̀yin ọmọ mi, tẹ́tí sí mi
fọkàn sí nǹkan tí mo sọ. 25Má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ kí ó yà sí ọ̀nà rẹ̀,
tàbí kí ó rìn lọ sí ipa ọ̀nà rẹ̀. 26Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí ó ti fà lulẹ̀.
Ogunlọ́gọ̀ àwọn alágbára ni ó ti pa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.