Native Bible

Proverbs 28:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọ̀kánjúwà ènìyàn a máa dá ìjà sílẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé Olúwa yóò gbilẹ̀.

Proverbs 28:25 in English

Proverbs 28:25 · Berean Standard Bible

A greedy man stirs up strife, but he who trusts in the LORD will prosper.

Context

23Ẹni tí ó bá ènìyàn kan wí yóò rí ojúrere ni nígbẹ̀yìn ju ẹni tí ó ní ètè ẹ̀tàn lọ. 24Ẹni tí ó ja baba tàbí ìyá rẹ̀ lólè tí ó sì wí pé, “Kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀,” irú kan ni òun àti ẹni tí ń pa ni run. 25Ọ̀kánjúwà ènìyàn a máa dá ìjà sílẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé Olúwa yóò gbilẹ̀. 26Ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀lé ara rẹ̀ jẹ́ aláìgbọ́n ṣùgbọ́n ẹni tí ń rìn nínú ọgbọ́n wà láìléwu. 27Ẹni tí ó ń fi fún tálákà kì yóò ṣe aláìní ohunkóhun, ṣùgbọ́n ẹni tí ó di ojú rẹ̀ sí wọn gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ègún.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.