Òwe 28:11
Proverbs 28:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọlọ́rọ̀ ènìyàn le è gbọ́n lójú ara rẹ̀ ṣùgbọ́n tálákà tí ó ní òye rí ìdí, rẹ̀.
Proverbs 28:11 in English
Proverbs 28:11 · Berean Standard Bible
A rich man is wise in his own eyes, but a poor man with discernment sees through him.
Context
9Bí ẹnikẹ́ni bá kọ etí ikún sí òfin,
kódà àdúrà rẹ̀ jẹ́ ìríra. 10Ẹni tí ó mú olódodo rìn ọ̀nà búburú
yóò bọ́ sínú pàkúté ara rẹ̀
ṣùgbọ́n aláìlẹ́gàn yóò gba ogún rere. 11Ọlọ́rọ̀ ènìyàn le è gbọ́n lójú ara rẹ̀
ṣùgbọ́n tálákà tí ó ní òye rí ìdí, rẹ̀. 12Nígbà tí olódodo ń lékè ariwo ayọ̀ ta;
ṣùgbọ́n nígbà tí ènìyàn búburú gorí òye, àwọn ènìyàn a na pápá bora. 13Ẹni tí ó bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ kì yóò ṣe rere,
ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ tí ó sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀ máa ń rí àánú gbà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.