Native Bible

Proverbs 27:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Jẹ́ kí ẹlòmíràn yìn ọ́ dípò ẹnu ara rẹ, àní àlejò, kí ó má sì ṣe ètè ìwọ fúnra rẹ̀.

Proverbs 27:2 in English

Proverbs 27:2 · Berean Standard Bible

Let another praise you, and not your own mouth— a stranger, and not your own lips.

Context

1Má ṣe yangàn nítorí ọ̀la nítorí o kò mọ ohun tí ọjọ́ kan le è mú wáyé. 2Jẹ́ kí ẹlòmíràn yìn ọ́ dípò ẹnu ara rẹ, àní àlejò, kí ó má sì ṣe ètè ìwọ fúnra rẹ̀. 3Òkúta wúwo, erùpẹ̀ sì wúwo ṣùgbọ́n ìbínú aṣiwèrè wúwo ju méjèèjì lọ. 4Ìbínú ni ìkà, ìrunú sì burú púpọ̀ ṣùgbọ́n ta ni ó le è dúró níwájú owú?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.