Native Bible

Proverbs 23:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Má ṣe jẹ oúnjẹ ẹni tí ó háwọ́, bẹ́ẹ̀ ni kí o má sì ṣe fẹ́ oúnjẹ dídùn rẹ̀.

Proverbs 23:6 in English

Proverbs 23:6 · Berean Standard Bible

Do not eat the bread of a stingy man,* and do not crave his delicacies;

Context

4Má ṣe ṣe làálàá láti lọ́rọ̀: ṣíwọ́ kúrò nínú ọgbọ́n ara rẹ. 5Ìwọ ó ha fi ojú rẹ lépa ohun tí kò sí? Nítorí tí ọ̀rọ̀ hu ìyẹ́ apá fún ara rẹ̀, ó sì ń fò bí idì ní ojú ọ̀run. 6Má ṣe jẹ oúnjẹ ẹni tí ó háwọ́, bẹ́ẹ̀ ni kí o má sì ṣe fẹ́ oúnjẹ dídùn rẹ̀. 7Nítorí pé bí ẹni tí ń ṣírò ní ọkàn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó rí: “Máa jẹ, kí o sì máa mu,” ni ó ń wí fún ọ; ṣùgbọ́n ọkàn rẹ̀ kò pẹ̀lú rẹ. 8Òkèlè tí ìwọ jẹ ni ìwọ ó pọ̀ jáde, ìwọ a sì sọ ọ̀rọ̀ dídùn rẹ̀ nù.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.